Matiu 8:5-20
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ìgbàgbọ́ balógun ọ̀rún
5 (A)Nígbà tí Jesu sì wọ̀ Kapernaumu, balógun ọ̀rún kan tọ̀ ọ́ wá, ó bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́. 6 O sì wí pé, “Olúwa, ọmọ ọ̀dọ̀ mi dùbúlẹ̀ ààrùn ẹ̀gbà ni ilé, tòun ti ìrora ńlá.”
7 Jesu sì wí fún un pé, “Èmi ń bọ̀ wá mú un láradá.”
8 Balógun ọ̀rún náà dáhùn, ó wí pé, “Olúwa, èmi kò yẹ ní ẹni tí ìwọ ń wọ̀ abẹ́ òrùlé rẹ̀, ṣùgbọ́n sọ kìkì ọ̀rọ̀ kan, a ó sì mú ọmọ ọ̀dọ̀ mi láradá. 9 Ẹni tí ó wà lábẹ́ àṣẹ sá ni èmi, èmi sí ní ọmọ-ogun lẹ́yìn mi. Bí mo wí fún ẹni kan pé, ‘Lọ,’ a sì lọ, àti fún ẹni kejì pé, ‘Wá,’ a sì wá, àti fún ọmọ ọ̀dọ̀ mi pé, ‘Ṣe èyí,’ a sì ṣe é.”
10 Nígbà tí Jesu gbọ́ èyí ẹnu yà á, ó sì wí fún àwọn tí ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, èmi kò rí ẹnìkan ni Israẹli tó ní ìgbàgbọ́ ńlá bí irú èyí. 11 Mo sì wí fún yín, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò ti ìhà ìlà-oòrùn àti ìhà ìwọ̀-oòrùn wá, wọ́n á sì bá Abrahamu àti Isaaki àti Jakọbu jẹun ní ìjọba ọ̀run. 12 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìjọba ni a ó sọ sínú òkùnkùn lóde, níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpayínkeke yóò gbé wà.”
13 Nítorí náà Jesu sì wí fún balógun ọ̀run náà pé, “Máa lọ ilé, ohun tí ìwọ gbàgbọ́ ti rí bẹ́ẹ̀.” A sì mú ọmọ ọ̀dọ̀ náà láradá ní wákàtí kan náà.
Jesu wo ọ̀pọ̀ aláìsàn sàn
14 (B)Nígbà tí Jesu sì dé ilé Peteru, ìyá ìyàwó Peteru dùbúlẹ̀ àìsàn ibà. 15 Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu fi ọwọ́ kan ọwọ́ rẹ̀, ibà náà fi í sílẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó sì dìde ó ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.
16 Nígbà tí ó di àṣálẹ́, ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ní ẹ̀mí èṣù ni a mú wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ lé àwọn ẹ̀mí èṣù náà jáde. A sì mú gbogbo àwọn ọlọ́kùnrùn láradá. 17 (C)Kí èyí tí a ti sọ láti ẹnu wòlíì Isaiah lè ṣẹ pé:
“Òun tìkára rẹ̀ gbà àìlera wa,
ó sì ń ru ààrùn wa.”
Ohun tí o gbà láti tẹ̀lé Jesu
18 (D)Nígbà tí Jesu rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tó yí i ká, ó pàṣẹ pé kí wọ́n rékọjá sí òdìkejì adágún. 19 Olùkọ́ òfin kan sì tọ̀ ọ́ wá, ó wí fún un pé, “Olùkọ́, èmi ó má tọ̀ ọ́ lẹ́yìn níbikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”
20 Jesu dá lóhùn pé, “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ni ìtẹ́; ṣùgbọ́n Ọmọ Ènìyàn kò ní ibi tí yóò fi orí rẹ̀ lé.”
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.